16. OLUWA si sọ fun Mose pe, Pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba Israeli jọ sọdọ mi, ẹniti iwọ mọ̀ pe, nwọn ṣe àgba awọn enia, ati olori wọn; ki o si mú wọn wá si agọ́ ajọ, ki nwọn ki o si duro nibẹ̀ pẹlu rẹ.
17. Emi o si sọkalẹ wá, emi o si bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀: emi o si mú ninu ẹmi ti mbẹ lara rẹ, emi o si fi i sara wọn; nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù awọn enia na, ki iwọ ki o máṣe nikan rù u.
18. Ki iwọ ki o si wi fun awọn enia na pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ dè ọla, ẹnyin o si jẹ ẹran: nitoriti ẹnyin sọkun li etí OLUWA, wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ? o sá dara fun wa ni Egipti: nitorina ni OLUWA yio ṣe fun nyin li ẹran, ẹnyin o si jẹ.
19. Ẹ ki o jẹ ni ijọ́ kan, tabi ni ijọ́ meji, tabi ni ijọ́ marun, bẹ̃ni ki iṣe ijọ́ mẹwa, tabi ogún ọjọ́;
20. Ṣugbọn li oṣù kan tọ̀tọ, titi yio fi yọ jade ni ihò-imu nyin, ti yio si fi sú nyin: nitoriti ẹnyin gàn OLUWA ti mbẹ lãrin nyin, ẹnyin si sọkun niwaju rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti awa fi jade lati Egipti wá?