Num 11:14-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Emi nikan kò le rù gbogbo awọn enia yi, nitoriti nwọn wuwo jù fun mi.

15. Ati bi bayi ni iwọ o ṣe si mi, emi bẹ̀ ọ, pa mi kánkan, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ; má si ṣe jẹ ki emi ri òṣi mi.

16. OLUWA si sọ fun Mose pe, Pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba Israeli jọ sọdọ mi, ẹniti iwọ mọ̀ pe, nwọn ṣe àgba awọn enia, ati olori wọn; ki o si mú wọn wá si agọ́ ajọ, ki nwọn ki o si duro nibẹ̀ pẹlu rẹ.

17. Emi o si sọkalẹ wá, emi o si bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀: emi o si mú ninu ẹmi ti mbẹ lara rẹ, emi o si fi i sara wọn; nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù awọn enia na, ki iwọ ki o máṣe nikan rù u.

18. Ki iwọ ki o si wi fun awọn enia na pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ dè ọla, ẹnyin o si jẹ ẹran: nitoriti ẹnyin sọkun li etí OLUWA, wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ? o sá dara fun wa ni Egipti: nitorina ni OLUWA yio ṣe fun nyin li ẹran, ẹnyin o si jẹ.

19. Ẹ ki o jẹ ni ijọ́ kan, tabi ni ijọ́ meji, tabi ni ijọ́ marun, bẹ̃ni ki iṣe ijọ́ mẹwa, tabi ogún ọjọ́;

20. Ṣugbọn li oṣù kan tọ̀tọ, titi yio fi yọ jade ni ihò-imu nyin, ti yio si fi sú nyin: nitoriti ẹnyin gàn OLUWA ti mbẹ lãrin nyin, ẹnyin si sọkun niwaju rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti awa fi jade lati Egipti wá?

21. Mose si wipe, Awọn enia na, lãrin awọn ẹniti emi wà, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀; iwọ si wipe, Emi o fun wọn li ẹran, ki nwọn ki o le ma jẹ li oṣù kan tọ̀tọ.

22. Agbo-ẹran tabi ọwọ́-ẹran ni ki a pa fun wọn, lati tó fun wọn ni? tabi gbogbo ẹja okun li a o kójọ fun wọn lati tó fun wọn?

23. OLUWA si sọ fun Mose pe, Ọwọ́ OLUWA ha kúru bi? iwọ o ri i nisisiyi bi ọ̀rọ mi yio ṣẹ si ọ, tabi bi ki yio ṣẹ.

Num 11