Num 11:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN enia na nṣe irahùn, nwọn nsọ ohun buburu li etí OLUWA: nigbati OLUWA si gbọ́ ọ, ibinu rẹ̀ si rú; iná OLUWA si ràn ninu wọn, o si run awọn ti o wà li opin ibudó na.

2. Awọn enia na si kigbe tọ̀ Mose lọ; nigbati Mose si gbadura si OLUWA, iná na si rẹlẹ.

3. O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Tabera: nitoriti iná OLUWA jó lãrin wọn.

4. Awọn adalú ọ̀pọ enia ti o wà pẹlu wọn ṣe ifẹkufẹ: awọn ọmọ Israeli pẹlu si tun sọkun wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ?

5. Awa ranti ẹja, ti awa ti njẹ ni Egipti li ọfẹ; ati apálà, ati bàra, ati ewebẹ, ati alubọsa, ati eweko:

6. Ṣugbọn nisisiyi ọkàn wa gbẹ: kò sí ohun kan rára, bikọse manna yi niwaju wa.

7. Manna na si dabi irugbìn korianderi, àwọ rẹ̀ si dabi àwọ okuta-bedeliumu.

8. Awọn enia na a ma lọ kakiri, nwọn a si kó o, nwọn a si lọ̀ ọ ninu ọlọ, tabi nwọn a si gún u ninu odó, nwọn a si sè e ninu ìkoko, nwọn a si fi din àkara: itọwò rẹ̀ si ri bi itọwò àkara oróro.

9. Nigbati ìri ba si sẹ̀ si ibudó li oru, manna a bọ́ si i.

10. Nigbana ni Mose gbọ́, awọn enia nsọkun ni idile wọn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ tirẹ̀: ibinu OLUWA si rú si wọn gidigidi; o si buru loju Mose.

11. Mose si wi fun OLUWA pe, Nitori kini iwọ fi npọ́n iranṣẹ rẹ loju? nitori kili emi kò si ṣe ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ fi dì ẹrù gbogbo enia yi lé mi?

12. Iṣe emi li o lóyun gbogbo enia yi? iṣe emi li o bi wọn, ti iwọ fi wi fun mi pe, Ma gbé wọn lọ li õkanaiya rẹ, bi baba iti igbé ọmọ ọmú, si ilẹ ti iwọ ti bura fun awọn baba wọn.

13. Nibo li emi o gbé ti mú ẹran wá fi fun gbogbo enia yi? nitoriti nwọn nsọkun si mi wipe, Fun wa li ẹran, ki awa ki o jẹ.

Num 11