Num 11:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN enia na nṣe irahùn, nwọn nsọ ohun buburu li etí OLUWA: nigbati OLUWA si gbọ́ ọ, ibinu rẹ̀ si rú; iná OLUWA si ràn ninu wọn, o si run awọn ti o wà li opin ibudó na.

2. Awọn enia na si kigbe tọ̀ Mose lọ; nigbati Mose si gbadura si OLUWA, iná na si rẹlẹ.

3. O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Tabera: nitoriti iná OLUWA jó lãrin wọn.

4. Awọn adalú ọ̀pọ enia ti o wà pẹlu wọn ṣe ifẹkufẹ: awọn ọmọ Israeli pẹlu si tun sọkun wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ?

5. Awa ranti ẹja, ti awa ti njẹ ni Egipti li ọfẹ; ati apálà, ati bàra, ati ewebẹ, ati alubọsa, ati eweko:

6. Ṣugbọn nisisiyi ọkàn wa gbẹ: kò sí ohun kan rára, bikọse manna yi niwaju wa.

7. Manna na si dabi irugbìn korianderi, àwọ rẹ̀ si dabi àwọ okuta-bedeliumu.

8. Awọn enia na a ma lọ kakiri, nwọn a si kó o, nwọn a si lọ̀ ọ ninu ọlọ, tabi nwọn a si gún u ninu odó, nwọn a si sè e ninu ìkoko, nwọn a si fi din àkara: itọwò rẹ̀ si ri bi itọwò àkara oróro.

9. Nigbati ìri ba si sẹ̀ si ibudó li oru, manna a bọ́ si i.

10. Nigbana ni Mose gbọ́, awọn enia nsọkun ni idile wọn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ tirẹ̀: ibinu OLUWA si rú si wọn gidigidi; o si buru loju Mose.

Num 11