Num 1:24-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ti awọn ọmọ Gadi, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

25. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Gadi, o jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ.

26. Ti awọn ọmọ Juda, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

27. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Juda, o jẹ́ ẹgbã mẹtadilogoji o le ẹgbẹ̀ta.

28. Ti awọn ọmọ Issakari, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

29. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Issakari, o jẹ́ ẹgbã mẹtadilọgbọ̀n o le irinwo.

30. Ti awọn ọmọ Sebuluni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

31. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Sebuluni, o jẹ́ ẹgbã mejidilọgbọ̀n o le egbeje.

32. Ti awọn ọmọ Josefu, eyinì ni, ti awọn ọmọ Efraimu, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

33. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Efraimu, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta.

34. Ti awọn ọmọ Manasse, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

35. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Manasse, o jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le igba.

36. Ti awọn ọmọ Benjamini, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

37. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Benjamini, o jẹ́ ẹgba mẹtadilogun o le egbeje.

38. Ti awọn ọmọ Dani, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

39. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Dani, o jẹ́ ẹgbã mọkanlelọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin.

40. Ti awọn ọmọ Aṣeri, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

41. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Aṣeri, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ.

42. Ti awọn ọmọ Naftali, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

Num 1