21. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Reubeni, o jẹ́ ẹgba mẹtalelogun o le ẹdẹgbẹta.
22. Ti awọn ọmọ Simeoni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;
23. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Simeoni, o jẹ́ ẹgba mọkandilọgbọ̀n o le ẹdegbeje.
24. Ti awọn ọmọ Gadi, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;
25. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Gadi, o jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ.
26. Ti awọn ọmọ Juda, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;
27. Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Juda, o jẹ́ ẹgbã mẹtadilogoji o le ẹgbẹ̀ta.
28. Ti awọn ọmọ Issakari, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;