1. LI ọjọ kẹrinlelogun oṣu yi, awọn ọmọ Israeli pejọ ninu àwẹ ati aṣọ ọ̀fọ, ati erupẹ lori wọn.
2. Awọn iru-ọmọ Israeli si ya ara wọn kuro ninu awọn ọmọ alejo, nwọn si duro, nwọn jẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati aiṣedede awọn baba wọn.
3. Nwọn si dide duro ni ipò wọn, nwọn si fi idamẹrin ọjọ kà ninu iwe ofin Oluwa Ọlọrun wọn; nwọn si fi idamẹrin jẹwọ, nwọn si sìn Oluwa Ọlọrun wọn.
4. Nigbana ni Jeṣua, ati Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani ati Kenani duro lori pẹtẹsì awọn ọmọ Lefi, nwọn si fi ohun rara kigbe si Oluwa Ọlọrun wọn.