7. Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemia, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordikai, Bilṣani, Mispereti, Bigfai, Nehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin enia Israeli li eyi;
8. Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbã o le mejilelãdọsan.
9. Awọn ọmọ Ṣefatiah, ojidinirinwo o le mejila.
10. Awọn ọmọ Ara, adọtalelẹgbẹta o le meji.
11. Awọn ọmọ Pahat-moabu, ti awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejidilogun.
12. Awọn ọmọ Elamu, ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.
13. Awọn ọmọ Sattu, ojilelẹgbẹrin o le marun.
14. Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin.
15. Awọn ọmọ Binnui, ojilelẹgbẹta o le mẹjọ.
16. Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mejidilọgbọn.
17. Awọn ọmọ Asgadi, egbejila o di mejidilọgọrin.
18. Awọn ọmọ Adonikamu ọtalelẹgbẹta o le meje.