Neh 7:59-73 Yorùbá Bibeli (YCE)

59. Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Amoni.

60. Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni jẹ irinwo din mẹjọ.

61. Awọn wọnyi li o si goke lati Telhariṣa, Kerubu, Addoni, ati Immeri wá: ṣugbọn nwọn kò le fi ile baba wọn hàn, tabi iran wọn, bi nwọn iṣe ti Israeli.

62. Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ojilelẹgbẹta ole meji.

63. Ati ninu awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Kosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o ni ọkan ninu awọn ọmọbinrin Barsillai, ara Gileadi, li aya, a si npè e nipa orukọ wọn.

64. Awọn wọnyi wá iwe orukọ wọn ninu awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn nipa idile ṣugbọn a kò ri i: nitorina li a ṣe yà wọn kurò ninu oyè alufa.

65. Bãlẹ na si wi fun wọn pe, ki nwọn máṣe jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi duro pẹlu Urimu, ati Tummimu,

66. Iye gbogbo ijọ jasi ẹgbãmọkanlelogun o le ojidinirinwo.

67. Laikà awọn iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹ-binrin wọn, iye wọn jẹ ẹgbẹtadilẹgbãrin o di ẹtalelọgọta: nwọn si ni ojilugba o le marun akọni ọkunrin ati akọni obinrin.

68. Ẹṣin wọn jẹ ọtadilẹgbẹrin o di mẹrin: ibaka nwọn jẹ ojilugba o le marun:

69. Rakumi jẹ ojilenirinwo o di marun: kẹtẹkẹtẹ jẹ ẹgbẹrinlelọgbọn o di ọgọrin.

70. Omiran ninu awọn olori ninu awọn baba fi nkan si iṣẹ na. Bãlẹ fi ẹgbẹrun dramu wura, ãdọta awokoto, ọrindilẹgbẹta le mẹwa ẹwu alufa sinu iṣura na.

71. Ninu awọn olori ninu awọn baba fi ọkẹ meji dramu wura, ati ẹgbọkanla mina fadaka si iṣura iṣẹ na.

72. Ati eyiti awọn enia iyokù mu wá jẹ ọkẹ meji dramu wura, ati ẹgbã mina fadaka, ati ẹwu alufa mẹtadilãdọrin.

73. Bẹ̃ni awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn oludena, ati awọn akọrin, ati ninu awọn enia, ati awọn Netinimu, ati gbogbo Israeli, ngbe ilu wọn; nigbati oṣu keje si pé, awọn ọmọ Israeli wà ni ilu wọn.

Neh 7