Neh 7:36-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.

37. Awọn ọmọ Lodi, Hadidi, ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le ọkan.

38. Awọn ọmọ Senaah ẹgbãji o di ãdọrin.

39. Awọn alufa: awọn ọmọ Jedaiah ti ile Jeṣua, ẹgbã o di mẹtadilọgbọn.

40. Awọn ọmọ Immeri, ẹgbẹrun o le mejilelãdọta.

41. Awọn ọmọ Paṣuri, ẹgbẹfa o le mẹtadiladọta.

42. Awọn ọmọ Harimu ẹgbẹrun o le mẹtadilogun.

Neh 7