Neh 7:33-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Awọn ọkunrin Nebo miran mejilelãdọta.

34. Awọn ọmọ Elamu miran ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.

35. Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.

36. Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.

37. Awọn ọmọ Lodi, Hadidi, ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le ọkan.

38. Awọn ọmọ Senaah ẹgbãji o di ãdọrin.

39. Awọn alufa: awọn ọmọ Jedaiah ti ile Jeṣua, ẹgbã o di mẹtadilọgbọn.

40. Awọn ọmọ Immeri, ẹgbẹrun o le mejilelãdọta.

41. Awọn ọmọ Paṣuri, ẹgbẹfa o le mẹtadiladọta.

42. Awọn ọmọ Harimu ẹgbẹrun o le mẹtadilogun.

43. Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua, ti Kadmieli, ninu ọmọ Hodafa, mẹrinlelãdọrin.

44. Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdọjọ.

45. Awọn oludena: awọn ọmọ Ṣallumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, mejidilogoje.

46. Awọn ọmọ Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Haṣufa, awọn ọmọ Tabbaoti,

Neh 7