30. Awọn ọkunrin Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun.
31. Awọn ọkunrin Mikmasi, mejilelọgọfa.
32. Awọn ọkunrin Beteli ati Ai, mẹtalelọgọfa.
33. Awọn ọkunrin Nebo miran mejilelãdọta.
34. Awọn ọmọ Elamu miran ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.
35. Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.
36. Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.
37. Awọn ọmọ Lodi, Hadidi, ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le ọkan.