11. Awọn ọmọ Pahat-moabu, ti awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejidilogun.
12. Awọn ọmọ Elamu, ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.
13. Awọn ọmọ Sattu, ojilelẹgbẹrin o le marun.
14. Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin.
15. Awọn ọmọ Binnui, ojilelẹgbẹta o le mẹjọ.
16. Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mejidilọgbọn.
17. Awọn ọmọ Asgadi, egbejila o di mejidilọgọrin.
18. Awọn ọmọ Adonikamu ọtalelẹgbẹta o le meje.
19. Awọn ọmọ Bigfai, ẹgbã o le mẹtadilãdọrin.
20. Awọn ọmọ Adini, ãdọtalelẹgbẹta o le marun.
21. Awọn ọmọ Ateri, ti Hesekiah mejidilọgọrun.
22. Awọn ọmọ Haṣamu, ọrindinirinwo o le mẹjọ.
23. Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹrin.
24. Awọn ọmọ Harifu mejilelãdọfa.
25. Awọn ọmọ Gibioni, marundilọgọrun.
26. Awọn ọkunrin Betlehemu ati Netofa, ọgọsan o le mẹjọ.