Neh 6:8-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nigbana ni mo ranṣẹ si i wipe, A kò ṣe iru eyi, ti iwọ sọ, ṣugbọn iwọ rò wọn li ọkàn ara rẹ ni.

9. Nitori gbogbo wọn mu wa bẹ̀ru, wipe, Ọwọ wọn yio rọ ninu iṣẹ na, ki a má le ṣe e. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun, mu ọwọ mi le.

10. Mo si wá si ile Ṣemaiah ọmọ Delaiah ọmọ Mehetabeeli, ti a há mọ, o si wipe, Jẹ ki a pejọ ni ile Ọlọrun ni inu tempili ki a si tì ilẹkùn tempili; nitori nwọn o wá lati pa ọ; nitõtọ, li oru ni nwọn o wá lati pa ọ.

11. Mo si wipe, Enia bi emi a ma sa? Tali o si dabi emi, ti o jẹ wọ inu tempili lọ lati gba ẹmi rẹ̀ là? Emi kì yio wọ̀ ọ lọ.

12. Sa kiyesi i, mo woye pe, Ọlọrun kò rán a, ṣugbọn pe, o nsọ asọtẹlẹ yi si mi: nitori Tobiah ati Sanballati ti bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ.

13. Nitorina li o ṣe bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ, ki emi ba foya, ki emi ṣe bẹ̃, ki emi si ṣẹ̀, ki nwọn le ri ihìn buburu rò, ki nwọn le kẹgàn mi.

Neh 6