Neh 6:17-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, awọn ijòye Juda ran iwe pupọ si Tobiah, iwe Tobiah si de ọdọ wọn.

18. Nitori ọ̀pọlọpọ ni Juda ti ba a mulẹ nitori ti o jẹ ana Sekaniah ọmọ Ara; ọmọ rẹ̀ Johanani si ti fẹ ọmọ Meṣullamu, ọmọ Berekiah.

19. Nwọn sọ̀rọ rere rẹ̀ pẹlu niwaju mi, nwọn si sọ ọ̀rọ mi fun u. Tobiah rán iwe lati da aiya já mi.

Neh 6