Neh 5:2-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nitori awọn kan wà ti nwọn wipe, Awa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, jẹ pipọ: nitorina awa gba ọkà, awa si jẹ, a si yè.

3. Awọn ẹlomiran wà pẹlu ti nwọn wipe, Awa ti fi oko wa, ọgba-ajara wa, ati ile wa, sọfa, ki awa ki o le rà ọkà ni ìgba ìyan.

4. Ẹlomiran si wipe, Awa ti ṣi owo lati san owo-ori ọba li ori oko wa, ati ọgba-ajara wa.

5. Ati sibẹ ẹran-ara wa si dabi ẹran-ara awọn arakunrin wa, ọmọ wa bi ọmọ wọn: si wo o, awa mu awọn arakunrin wa ati awọn arabinrin wa wá si oko-ẹrú, lati jẹ iranṣẹ, a si ti mu ninu awọn ọmọbinrin wa wá si oko-ẹrú na: awa kò ni agbara lati rà wọn padà: nitori awọn ẹlomiran li o ni oko wa ati ọgbà ajara wa.

6. Emi si binu gidigidi nigbati mo gbọ́ igbe wọn ati ọ̀rọ wọnyi.

Neh 5