11. Mo bẹ̀ nyin, ẹ fi oko wọn, ọgbà-ajarà wọn, ọgbà-olifi wọn, ati ile wọn, ida-ọgọrun owo na pẹlu, ati ti ọkà, ọti-waini, ati ororo wọn, ti ẹ fi agbara gbà, fun wọn padà loni yi.
12. Nwọn si wipe, Awa o fi fun wọn pada, awa kì yio si bere nkankan lọwọ wọn; bẹ̃li awa o ṣe bi iwọ ti wi. Nigbana ni mo pe awọn alufa, mo si mu wọn bura pe, nwọn o ṣe gẹgẹ bi ileri yi.
13. Mo si gbọ̀n apo aṣọ mi, mo si wipe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o gbọ̀n olukuluku enia kuro ni ile rẹ̀, ati kuro ninu iṣẹ rẹ̀, ti kò mu ileri yi ṣẹ, ani bayi ni ki a gbọ̀n ọ kuro, ki o si di ofo. Gbogbo ijọ si wipe, Amin! nwọn si fi iyìn fun Oluwa. Awọn enia na si ṣe gẹgẹ bi ileri yi.
14. Pẹlupẹlu lati akoko ti a ti yàn mi lati jẹ bãlẹ wọn ni ilẹ Juda, lati ogún ọdun titi de ọdun kejilelọgbọn Artasasta ọba, eyinì ni, ọdun mejila, emi ati awọn arakunrin mi kò jẹ onjẹ bãlẹ.