Neh 5:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN enia ati awọn aya wọn si nkigbe nlanla si awọn ara Juda, arakunrin wọn.

2. Nitori awọn kan wà ti nwọn wipe, Awa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, jẹ pipọ: nitorina awa gba ọkà, awa si jẹ, a si yè.

3. Awọn ẹlomiran wà pẹlu ti nwọn wipe, Awa ti fi oko wa, ọgba-ajara wa, ati ile wa, sọfa, ki awa ki o le rà ọkà ni ìgba ìyan.

4. Ẹlomiran si wipe, Awa ti ṣi owo lati san owo-ori ọba li ori oko wa, ati ọgba-ajara wa.

5. Ati sibẹ ẹran-ara wa si dabi ẹran-ara awọn arakunrin wa, ọmọ wa bi ọmọ wọn: si wo o, awa mu awọn arakunrin wa ati awọn arabinrin wa wá si oko-ẹrú, lati jẹ iranṣẹ, a si ti mu ninu awọn ọmọbinrin wa wá si oko-ẹrú na: awa kò ni agbara lati rà wọn padà: nitori awọn ẹlomiran li o ni oko wa ati ọgbà ajara wa.

6. Emi si binu gidigidi nigbati mo gbọ́ igbe wọn ati ọ̀rọ wọnyi.

7. Mo si ronu ọ̀ran na, mo si ba awọn ijoye ati awọn olori wi, mo si wi fun wọn pe, Ẹnyin ngba ẹdá olukuluku lọwọ arakunrin rẹ̀. Mo si pe apejọ nla tì wọn.

Neh 5