Neh 4:14-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Mo si wò, mo si dide, mo si wi fun awọn ìjoye, ati fun awọn olori, ati fun awọn enia iyokù pe, Ẹ máṣe jẹ ki ẹ̀ru wọn bà nyin, ẹ ranti Oluwa ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ki ẹ si jà fun awọn arakunrin nyin, awọn ọmọkunrin nyin, ati awọn ọmọbinrin nyin, awọn aya nyin, ati ile nyin.

15. O si ṣe, nigbati awọn ọta wa gbọ́ pe, o di mimọ̀ fun wa, Ọlọrun ti sọ ìmọ wọn di asan, gbogbo wa si padà si odi na, olukuluku si iṣẹ rẹ̀.

16. O si ṣe, lati ọjọ na wá, idaji awọn ọmọkunrin mi ṣe iṣẹ na, idaji keji di ọ̀kọ, apata, ati ọrun, ati ihamọra mu; awọn olori si duro lẹhin gbogbo ile Juda.

17. Awọn ti nmọ odi, ati awọn ti nrù ẹrù ati awọn ti o si ndi ẹrù, olukuluku wọn nfi ọwọ rẹ̀ kan ṣe iṣẹ, nwọn si fi ọwọ keji di ohun ìja mu.

18. Olukuluku awọn ọmọ kọ́ idà rẹ̀ li ẹgbẹ rẹ̀, bẹni nwọn si mọ odi. Ẹniti nfọn ipè wà li eti ọdọ mi.

19. Mo si sọ fun awọn ijoye, ati fun awọn olori, ati fun awọn enia iyokù pe, Iṣẹ́ na tobi o si pọ̀, a si ya ara wa lori odi, ẹnikini jina si ẹnikeji.

20. Ni ibi ti ẹnyin ba gbọ́ iro ipè, ki ẹ wá sọdọ wa: Ọlọrun wa yio jà fun wa.

21. Bẹ̃ni awa ṣe iṣẹ na: idaji wọn di ọ̀kọ mu lati kùtukutu owurọ titi irawọ fi yọ.

22. Li àkoko kanna pẹlu ni mo sọ fun awọn enia pe, Jẹ ki olukuluku pẹlu ọmọkunrin rẹ̀ ki o sùn ni Jerusalemu, ki nwọn le jẹ ẹṣọ fun wa li oru, ki nwọn si le ṣe iṣẹ li ọsan.

23. Bẹ̃ni kì iṣe emi, tabi awọn arakunrin mi, tabi awọn ọmọkunrin mi, tabi awọn oluṣọ ti ntọ̀ mi lẹhin, kò si ẹnikan ninu wa ti o bọ́ aṣọ kuro, olukuluku mu ohun ìja rẹ̀ li ọwọ fun ogun.

Neh 4