1. O SI ṣe, nigbati Sanballati gbọ́ pe awa mọ odi na, inu rẹ̀ rú, o si binu pupọ, o si gàn awọn ara Juda.
2. O si sọ niwaju awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ-ogun Samaria pe, Kini awọn alailera Juda wọnyi nṣe yi? nwọn o ha dá wà fun ara wọn bi? nwọn o ha rubọ? nwọn o ha ṣe aṣepari ni ijọkan? nwọn o ha mu okuta ti a ti sun lati inu okìti sọji?
3. Tobiah ara Ammoni si wà li eti ọ̀dọ rẹ̀, o si wipe, Eyi ti nwọn mọ gidi, bi kọ̀lọkọlọ ba gùn u, yio tilẹ wo odi okuta wọn lulẹ̀.
4. Gbọ́, Ọlọrun wa; nitoriti awa di ẹni ẹ̀gan: ki iwọ ki o si dà ẹgan wọn si ori ara wọn, ki o si fi wọn fun ikogun ni ilẹ ìgbekun.
5. Ki o má si bo irekọja wọn, má si jẹ ki a wẹ ẹ̀ṣẹ wọn nù kuro niwaju rẹ: nitoriti nwọn bi ọ ni inu niwaju awọn ọ̀mọle,
6. Bẹ̃ni awa mọ odi na: gbogbo odi na ni a si mọ kàn ara wọn titi de ida meji rẹ̀: nitori awọn enia na ni ọkàn lati ṣiṣẹ.
7. O si ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati awọn ara Arabia, ati awọn ara Ammoni, ati awọn ara Aṣdodi gbọ́ pe, a mọ odi Jerusalemu de oke, ati pe a bẹ̀rẹ si tun ibi ti o ya ṣe, inu wọn ru gidigidi.
8. Gbogbo wọn si jọ gbìmọ pọ̀ lati wá iba Jerusalemu jà, ati lati ṣe ika si i.
9. Ṣugbọn awa gba adura wa si Ọlọrun wa, a si yan iṣọ si wọn lọsan ati loru, nitori wọn.
10. Juda si wipe, Agbara awọn ti nru ẹrù dínkù, àlapa pupọ li o wà, tobẹ̃ ti awa kò fi le mọ odi na.
11. Awọn ọta wa si wipe, Nwọn kì yio mọ̀, bẹ̃ni nwọn kì yio ri titi awa o fi de ãrin wọn, ti a o fi pa wọn, ti a o si da iṣẹ na duro.
12. O si ṣe, nigbati awọn ara Juda ti o wà li agbegbe wọn de, nwọn wi fun wa nigba mẹwa pe, Lati ibi gbogbo wá li ẹnyin o pada tọ̀ wa wá.