5. Ati lọwọkọwọ wọn ni awọn ará Tekoa tun ṣe, ṣugbọn awọn ọlọla kò fi ọrùn si iṣẹ Oluwa wọn.
6. Jehoida, ọmọ Pasea, ati Meṣullamu, ọmọ Besodiah, si tun ẹnu-bode atijọ ṣe, nwọn tẹ̀ igi idabu rẹ̀, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, ati àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀.
7. Lọwọkọwọ wọn ni Melatiah, ará Gibeoni, tun ṣe, ati Jadoni, ara Merono, awọn ọkunrin ti Gibeoni, ati ti Mispa, ti o jẹ ti itẹ bãlẹ̀ apa ihin odò.
8. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Ussieli ọmọ Harhiah, alagbẹdẹ wura tun ṣe; ati lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hananiah ọmọ alapolu, tun ṣe; nwọn si ti fi Jerusalemu silẹ̀ titi de odi gbigbõro.
9. Lọwọkọwọ wọn ni Refaiah, ọmọ Huri ijòye idaji Jerusalemu si tun ṣe.
10. Lọwọkọwọ wọn ni Jedaiah, ọmọ Haramafu, si tun ṣe, ani ọkánkan ile rẹ̀. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hattuṣi ọmọ Haṣabaniah si tun ṣe.