11. Malkijah ọmọ Harimu, ati Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu, tun apa keji ṣe, ati ile-iṣọ ileru.
12. Ati lọwọkọwọ rẹ̀ Ṣallumu ọmọ Haloheṣi, ijòye apa kan Jerusalemu, tun ṣe, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀.
13. Hanuni pẹlu awọn ará Sanoa si tun ẹnu-bode afonifoji ṣe; nwọn kọ́ ọ, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itikùn rẹ̀, ati ẹgbẹrun igbọnwọ odi titi de ẹnu-bode ãtàn.
14. Ẹnu-bode ãtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, ijòye apa kan Bet-hakkeremu tun ṣe; o kọ́ ọ, o gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itìkun rẹ̀.
15. Ṣallumu, ọmọ Kol-hose, ijòye apakan Mispa si tun ẹnu-bode orisun ṣe; o kọ́ ọ, o si bò o, o si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itìkun rẹ̀ ati odi adagun Ṣiloa li ẹ̀ba ọgba ọba, ati titi de atẹ̀gun ti o sọkalẹ lati ile Dafidi lọ.
16. Lẹhin rẹ̀ ni Nehemiah, ọmọ Asbuku, ijòye idaji Bet-huri, tun ṣe titi de ibi ọkánkán iboji Dafidi, ati de adagun ti a ṣe, ati titi de ile awọn alagbara.
17. Lẹhin rẹ̀ ni awọn ọmọ Lefi, Rehumu, ọmọ Bani tun ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Haṣabiah ijòye idaji Keila tun ṣe li apa tirẹ̀.