Neh 2:3-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Mo si wi fun ọba pe, Ki ọba ki o pẹ: ẽṣe ti oju mi kì yio fi faro, nigbati ilu, ile iboji awọn baba mi dahoro, ti a si fi iná sun ilẹkun rẹ̀?

4. Nigbana ni ọba wi fun mi pe, ẹ̀bẹ kini iwọ fẹ bẹ̀? Bẹ̃ni mo gbadura si Ọlọrun ọrun.

5. Mo si wi fun ọba pe, Bi o ba wù ọba, ati bi iranṣẹ rẹ ba ri ojurere lọdọ rẹ, ki iwọ le rán mi lọ si Juda, si ilu iboji awọn baba mi, ki emi ki o ba le kọ́ ọ.

6. Ọba si wi fun mi pe, (ayaba si joko tì i) ajo rẹ yio ti pẹ to? nigbawo ni iwọ o si pada? Bẹli o wù ọba lati rán mi; mo si dá àkoko kan fun u.

7. Pẹlupẹlu mo wi fun ọba pe, bi o ba wù ọba, ki o fun mi ni iwe si awọn bãlẹ li oke odò, ki nwọn le mu mi kọja titi emi o fi de Juda;

8. Ati iwe kan fun Asafu, oluṣọ igbo ọba, ki o le fun mi ni igi fun atẹrigba ẹnu-ọ̀na odi lẹba ile Ọlọrun ati fun odi ilu, ati fun ile ti emi o wọ̀. Ọba si fun mi gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun mi lara mi.

9. Nigbana ni mo de ọdọ awọn bãlẹ li oke odo mo si fi iwe ọba fun wọn: Ọba si ti rán awọn olori-ogun ati ẹlẹṣin pẹlu mi.

10. Nigbati Sanballati ara Horoni ati Tobiah iranṣẹ ara Ammoni gbọ́, o bi wọn ni inu gidigidi pe, enia kan wá lati wá ire awọn ọmọ Israeli.

11. Bẹni mo de Jerusalemu, mo si wà nibẹ̀ ni ọjọ mẹta.

12. Mo si dide li oru, emi ati ọkunrin diẹ pẹlu mi: emi kò si sọ fun enia kan ohun ti Ọlọrun mi fi si mi li ọkàn lati ṣe ni Jerusalemu: bẹni kò si ẹranko kan pẹlu mi, bikoṣe ẹranko ti mo gùn.

13. Mo si jade li oru ni ibode afonifoji, ani niwaju kanga Dragoni, ati li ẹnu-ọ̀na ãtàn; mo si wò odi Jerusalemu ti a wó lulẹ̀, ati ẹnu-ọ̀na ti a fi iná sun.

14. Nigbana ni mo lọ si ẹnu-ọ̀na orisun, ati si àbata ọba: ṣugbọn kò si àye fun ẹranko ti mo gun lati kọja.

15. Nigbana ni mo goke lọ li oru lẹba odò, mo si wò odi na: mo si yipada, mo si tún wọ̀ bode afonifoji, mo si yipada.

16. Awọn ijoye kò si mọ̀ ibi ti mo lọ, tabi ohun ti mo ṣe; emi kò ti isọ fun awọn ara Juda tabi fun awọn alufa, tabi fun awọn alagba, tabi fun awọn ijoye; tabi fun awọn iyokù ti o ṣe iṣẹ na.

Neh 2