Neh 2:11-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Bẹni mo de Jerusalemu, mo si wà nibẹ̀ ni ọjọ mẹta.

12. Mo si dide li oru, emi ati ọkunrin diẹ pẹlu mi: emi kò si sọ fun enia kan ohun ti Ọlọrun mi fi si mi li ọkàn lati ṣe ni Jerusalemu: bẹni kò si ẹranko kan pẹlu mi, bikoṣe ẹranko ti mo gùn.

13. Mo si jade li oru ni ibode afonifoji, ani niwaju kanga Dragoni, ati li ẹnu-ọ̀na ãtàn; mo si wò odi Jerusalemu ti a wó lulẹ̀, ati ẹnu-ọ̀na ti a fi iná sun.

14. Nigbana ni mo lọ si ẹnu-ọ̀na orisun, ati si àbata ọba: ṣugbọn kò si àye fun ẹranko ti mo gun lati kọja.

15. Nigbana ni mo goke lọ li oru lẹba odò, mo si wò odi na: mo si yipada, mo si tún wọ̀ bode afonifoji, mo si yipada.

16. Awọn ijoye kò si mọ̀ ibi ti mo lọ, tabi ohun ti mo ṣe; emi kò ti isọ fun awọn ara Juda tabi fun awọn alufa, tabi fun awọn alagba, tabi fun awọn ijoye; tabi fun awọn iyokù ti o ṣe iṣẹ na.

17. Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Ẹnyin ri ibanujẹ ti awa wà, bi Jerusalemu ti di ahoro, ẹnu-ọ̀na rẹ̀ li a si fi iná sun: ẹ wá, ẹ jẹ ki a mọ odi Jerusalemu, ki a má ba jẹ ẹni-ẹgàn mọ!

Neh 2