Neh 2:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li oṣu Nisani, li ogún ọdun Artasasta ọba, ọti-waini wà niwaju rẹ̀: mo si gbe ọti-waini na, mo si fi fun ọba. Emi kò si ti ifajuro niwaju rẹ̀ rí.

2. Nitorina ni ọba ṣe wi fun mi pe, ẽṣe ti oju rẹ fi faro? iwọ kò sa ṣaisan? eyi kì iṣe ohun miran bikoṣe ibanujẹ. Ẹ̀ru si ba mi gidigidi.

3. Mo si wi fun ọba pe, Ki ọba ki o pẹ: ẽṣe ti oju mi kì yio fi faro, nigbati ilu, ile iboji awọn baba mi dahoro, ti a si fi iná sun ilẹkun rẹ̀?

4. Nigbana ni ọba wi fun mi pe, ẹ̀bẹ kini iwọ fẹ bẹ̀? Bẹ̃ni mo gbadura si Ọlọrun ọrun.

Neh 2