Neh 13:7-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Mo si wá si Jerusalemu, mo si mọ̀ buburu ti Eliaṣibu ṣe nitori Tobiah, ni pipèse iyẹwu fun u, ninu àgbala ile Ọlọrun.

8. O si bà mi ninu jẹ gidigidi, nitorina mo da gbogbo ohun èlo Tobiah jade kuro ninu iyẹwu na.

9. Nigbana ni mo paṣẹ, nwọn si wẹ̀ iyẹwu na mọ: si ibẹ ni mo si tun mu ohun èlo ile Ọlọrun wá, pẹlu ẹbọ ohun jijẹ ati turari.

10. Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀.

11. Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn.

12. Nigbana ni gbogbo Juda mu idamẹwa ọka ati ọti-waini titun ati ororo wá si ile iṣura.

13. Mo si yàn olupamọ si ile iṣura, Ṣelemiah alufa ati Sadoku akọwẹ, ati ninu awọn ọmọ Lefi, Pedaiah: ati lọwọkọwọ wọn ni Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah: nitoriti a kà wọn si olõtọ, iṣẹ́ wọn si ni lati ma pin fun awọn arakunrin wọn.

14. Ranti mi, Ọlọrun mi, nitori eyi, ki o má si nu iṣẹ rere ti mo ti ṣe fun ile Ọlọrun mi, nu kuro, ati fun akiyesi rẹ̀.

15. Li ọjọ wọnni ni mo ri awọn kan ti nfunti ni Juda li ọjọ isimi, awọn ti nmu iti ọka wale, ti ndi ẹrù rù kẹtẹkẹtẹ; ti ọti-waini, pẹlu eso àjara, ati eso ọ̀pọtọ, ati gbogbo oniruru ẹrù ti nwọn nmu wá si Jerusalemu li ọjọ isimi: mo si jẹri gbè wọn li ọjọ ti nwọn ntà ohun jijẹ.

16. Awọn ara Tire ngbe ibẹ pẹlu, ti nwọn mu ẹja, ati oniruru ohun èlo wá, nwọn si ntà li ọjọ isimi fun awọn ọmọ Juda, ati ni Jerusalemu.

17. Nigbana ni mo ba awọn ijoye Juda jà, mo si wi fun wọn pe, ohun buburu kili ẹnyin nṣe yi, ti ẹ si mba ọjọ isimi jẹ.

Neh 13