21. Nigbana ni mo jẹri gbè wọn, mo si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi sùn lẹhin odi, bi ẹnyin ba tun ṣe bẹ̃, emi o fọwọ bà nyin. Lati àkoko na lọ ni nwọn kò si wá lọjọ isimi mọ.
22. Mo si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ya ara wọn si mimọ, ki nwọn si wa ṣọ ẹnu-bode lati pa ọjọ isimi mọ. Ranti mi Ọlọrun mi nitori eyi pẹlu, ki o si da mi si gẹgẹ bi ọ̀pọ ãnu rẹ.
23. Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, mo ri ara Juda ti mba obinrin awọn ara Aṣdodi, Ammoni, ati ti Moabu gbe:
24. Awọn ọmọ wọn si nsọ apakan ède Aṣdodi, nwọn kò si le sọ̀rọ li ède awọn ara Juda, ṣugbọn gẹgẹ bi ède olukuluku.
25. Mo si ba wọn jà, mo gàn wọn, mo lù ninu wọn, mo tu irun wọn, mo mu wọn fi Ọlọrun bura pe, Ẹnyin kì yio fi ọmọbinrin nyin fun ọmọkunrin nwọn, tabi ọmọbinrin nwọn fun ọmọkunrin nyin tabi fun ara nyin.
26. Solomoni ọba Israeli kò ha dẹṣẹ nipa nkan wọnyi? Bẹ̃ni li ãrin orilẹ-ède pupọ, kò si ọba kan bi on ti Ọlọrun rẹ̀ fẹràn; Ọlọrun si fi jẹ ọba li ori gbogbo Israeli, bẹ̃ni on li awọn àjeji obinrin mu ki o ṣẹ̀.
27. Njẹ ki awa ha gbọ́ ti nyin, lati ṣe gbogbo buburu nla yi, lati ṣẹ̀ si Ọlọrun sa, ni gbigbe awọn àjeji obinrin ni iyawo?
28. Ati ọkan ninu awọn ọmọ Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olori alufa, jẹ ana Sanballati, ara Horoni, nitori na mo le e kuro lọdọ mi.
29. Ranti wọn, Ọlọrun mi, nitoriti nwọn ti ba oyè alufa jẹ, pẹlu majẹmu oyè-alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi.
30. Bayi ni mo wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo awọn alejo, mo si yan ẹ̀ṣọ awọn alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi, olukuluku ninu iṣẹ tirẹ̀.
31. Ati fun ẹ̀bun igi li àkoko ti a yàn, ati fun akọso. Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere.