Neh 13:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọjọ na, a kà ninu iwe Mose li eti gbogbo enia, ati ninu rẹ̀ li a ri pe, ki ara Ammoni ati ara Moabu ki o má wá sinu ijọ Ọlọrun lailai;

2. Nitoriti nwọn kò fi onjẹ ati omi ko awọn ọmọ Israeli lọna, ṣugbọn nwọn bẹ̀ Balaamu lọwẹ si wọn, lati fi wọn gegun: ṣugbọn Ọlọrun wa sọ egun na di ibukun.

3. O si ṣe, nigbati nwọn ti gbọ́ ofin na, ni nwọn yà gbogbo awọn ọ̀pọ enia ti o darapọ̀ mọ Israeli kuro.

4. Ati ṣaju eyi, Eliaṣibu alufa, ti o jẹ alabojuto iyẹwu ile Ọlọrun wa jẹ ana Tobiah.

5. O si ti pèse iyẹwu nla kan fun u, nibiti nwọn ima fi ẹbọ ohun jijẹ, turari, ati ohun èlo, ati idamẹwa agbado, ọti-waini titun, ati ororo si nigba atijọ, eyi ti a pa li aṣẹ lati fi fun awọn ọmọ Lefi, ati awọn akọrin, ati awọn adèna: ati ẹbọ ọrẹ awọn alufa.

6. Ṣugbọn ni gbogbo àkoko yi, emi kò si ni Jerusalemu: nitori li ọdun kejilelọgbọn ti Artasasta ọba Babiloni, mo wá si ọdọ ọba, ati li opin ọjọ wọnni, mo gba àye lati ọdọ ọba.

7. Mo si wá si Jerusalemu, mo si mọ̀ buburu ti Eliaṣibu ṣe nitori Tobiah, ni pipèse iyẹwu fun u, ninu àgbala ile Ọlọrun.

8. O si bà mi ninu jẹ gidigidi, nitorina mo da gbogbo ohun èlo Tobiah jade kuro ninu iyẹwu na.

9. Nigbana ni mo paṣẹ, nwọn si wẹ̀ iyẹwu na mọ: si ibẹ ni mo si tun mu ohun èlo ile Ọlọrun wá, pẹlu ẹbọ ohun jijẹ ati turari.

10. Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀.

11. Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn.

Neh 13