3. Wọnyi si ni awọn olori igberiko ti ngbe Jerusalemu, ṣugbọn ninu ilu Juda, olukuluku ngbe inu ilẹ ìni rẹ̀ ninu ilu wọn, eyini ni: awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni.
4. Ati ninu awọn ọmọ Juda ngbe Jerusalemu, ati ninu awọn ọmọ Benjamini. Ninu awọn ọmọ Juda, Ataiah ọmọ Ussiah, ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Mahalaleeli, ninu awọn ọmọ Peresi;
5. Ati Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Kol-hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣiloni.
6. Gbogbo ọmọ Peresi ti ngbe Jerusalemu jẹ adọrinlenirinwo o di meji, alagbara ọkunrin.
7. Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini; Sallu ọmọ Meṣullamu ọmọ Joedi, ọmọ Pedaiah, ọmọ Kolaiah, ọmọ Maaseiah, ọmọ Itieli, ọmọ Jesaiah.
8. Ati lẹhin rẹ̀ Gabbai, Sallai, ọrindilẹgbẹrun o le mẹjọ.
9. Joeli ọmọ Sikri si ni alabojuto wọn; ati Juda ọmọ Senua ni igbakeji ni ilu.
10. Ninu awọn alufa: Jedaiah ọmọ Joiaribu, Jakini.
11. Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitibu, ni olori ile Ọlọrun.
12. Awọn arakunrin wọn ti o ṣe iṣẹ ile na jẹ, ẹgbẹrin o le mejilelogun: ati Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelaliah, ọmọ Amsi, ọmọ Sekariah, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah,
13. Ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn olori awọn baba, ojilugba o le meji: ati Amaṣai ọmọ Asareeli, ọmọ Ahasai, ọmọ Meṣillemoti, ọmọ Immeri,
14. Ati awọn arakunrin wọn, alagbara li ogun, mejidilãdoje: ati olori wọn ni Sabdieli ọmọ ọkan ninu awọn enia nla.
15. Ninu awọn ọmọ Lefi pẹlu: Ṣemaiah, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Bunni;