22. Ati alabojuto awọn ọmọ Lefi ni Jerusalemu ni Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mika. Ninu awọn ọmọ Asafu, awọn akọrin wà lori iṣẹ ile Ọlọrun.
23. Nitori o jẹ aṣẹ ọba nipa ti wọn, pe ki ipin kan ti o yẹ ki o jẹ ti awọn akọrin, li ojojumọ.
24. Ati Petahiah ọmọ Meṣesabeeli ninu awọn ọmọ Serah ọmọ Juda wà li ọwọ ọba ninu gbogbo awọn enia.
25. Ati fun ileto, pẹlu oko wọn, ninu awọn ọmọ Juda ngbe Kirjat-arba, ati ileto rẹ̀, ati ni Diboni, ati ileto rẹ̀, ati ni Jekabseeli, ati ileto rẹ̀,
26. Ati ni Jeṣua, ati ni Molada, ati ni Bet-feleti,
27. Ati ni Hasar-ṣuali, ati ni Beerṣeba, ati ileto rẹ̀,
28. Ati ni Siklagi, ati ni Mekona, ati ninu ileto rẹ̀,
29. Ati ni En-rimmoni, ati ni Sarea, ati Jarmuti,
30. Sanoa, Adullamu, ati ileto wọn, ni Lakiṣi, ati oko rẹ̀, ni Aseka, ati ileto rẹ̀. Nwọn si ngbe lati Beerṣeba titi de afonifoji Hinnomu.
31. Ati awọn ọmọ Benjamini lati Geba de Mikmaṣi, ati Aija, ati Beteli, ati ileto wọn.