Neh 11:22-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ati alabojuto awọn ọmọ Lefi ni Jerusalemu ni Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mika. Ninu awọn ọmọ Asafu, awọn akọrin wà lori iṣẹ ile Ọlọrun.

23. Nitori o jẹ aṣẹ ọba nipa ti wọn, pe ki ipin kan ti o yẹ ki o jẹ ti awọn akọrin, li ojojumọ.

24. Ati Petahiah ọmọ Meṣesabeeli ninu awọn ọmọ Serah ọmọ Juda wà li ọwọ ọba ninu gbogbo awọn enia.

25. Ati fun ileto, pẹlu oko wọn, ninu awọn ọmọ Juda ngbe Kirjat-arba, ati ileto rẹ̀, ati ni Diboni, ati ileto rẹ̀, ati ni Jekabseeli, ati ileto rẹ̀,

26. Ati ni Jeṣua, ati ni Molada, ati ni Bet-feleti,

Neh 11