19. Ati awọn adèna, Akkubu, Talmoni, ati awọn arakunrin wọn ti nṣọ ẹnu ọ̀na jẹ mejilelãdọsan.
20. Ati iyokù Israeli, ti awọn alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi, wà ni gbogbo ilu Juda, olukuluku ninu ilẹ ìni rẹ̀.
21. Ṣugbọn awọn Netinimu ngbe Ofeli: ati Siha, ati Gispa wà li olori awọn Netinimu.
22. Ati alabojuto awọn ọmọ Lefi ni Jerusalemu ni Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mika. Ninu awọn ọmọ Asafu, awọn akọrin wà lori iṣẹ ile Ọlọrun.
23. Nitori o jẹ aṣẹ ọba nipa ti wọn, pe ki ipin kan ti o yẹ ki o jẹ ti awọn akọrin, li ojojumọ.
24. Ati Petahiah ọmọ Meṣesabeeli ninu awọn ọmọ Serah ọmọ Juda wà li ọwọ ọba ninu gbogbo awọn enia.