Neh 11:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN olori awọn enia si ngbe Jerusalemu: awọn enia iyokù si dìbo lati mu ẹnikan ninu ẹnimẹwa lati ma gbe Jerusalemu, ilu mimọ́, ati mẹsan iyokù lati ma gbe ilu miran.

2. Awọn enia si sure fun gbogbo awọn ọkunrin na ti nwọn yan ara wọn lati gbe Jerusalemu.

3. Wọnyi si ni awọn olori igberiko ti ngbe Jerusalemu, ṣugbọn ninu ilu Juda, olukuluku ngbe inu ilẹ ìni rẹ̀ ninu ilu wọn, eyini ni: awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni.

4. Ati ninu awọn ọmọ Juda ngbe Jerusalemu, ati ninu awọn ọmọ Benjamini. Ninu awọn ọmọ Juda, Ataiah ọmọ Ussiah, ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Mahalaleeli, ninu awọn ọmọ Peresi;

5. Ati Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Kol-hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣiloni.

Neh 11