20. Magpiaṣi, Meṣullamu, Hasiri,
21. Meṣesabeeli, Sadoku, Jaddua,
22. Pelatiah, Hanani, Anaiah,
23. Hoṣea, Hananiah, Haṣubu,
24. Halloheṣi, Pileha, Ṣobeki,
25. Rehumu, Hasabna, Maaseiah,
26. Ati Ahijah, Hanani, Anani,
27. Malluku, Harimu, Baana.
28. Ati awọn enia iyokù, awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, awọn adèna, awọn akọrin, awọn Netinimu, ati gbogbo awọn ti o ya ara wọn kuro lọdọ awọn enia ilẹ na si ofin Ọlọrun, aya wọn, awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo ẹniti o ni ìmọ ati oye;
29. Nwọn faramọ awọn arakunrin wọn, awọn ijoye wọn, nwọn si wọ inu èpe ati ibura, lati ma rìn ninu ofin Ọlọrun, ti a fi lelẹ nipa ọwọ Mose iranṣẹ Ọlọrun, lati kiyesi, ati lati ṣe gbogbo aṣẹ Jehofah, Oluwa wa, ati idajọ rẹ̀, ati ilana rẹ̀;