Neh 1:10-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Njẹ awọn wọnyi ni awọn iranṣẹ rẹ ati enia rẹ, ti iwọ ti rà pada nipa agbara rẹ nla ati nipa ọwọ agbara rẹ.

11. Oluwa, emi bẹ ọ, tẹ́ eti rẹ silẹ si adura iranṣẹ rẹ, ati si adura awọn iranṣẹ rẹ, ti o fẹ lati bẹ̀ru orukọ rẹ: emi bẹ ọ, ki o si ṣe rere si iranṣẹ rẹ loni, ki o si fun u li ãnu li oju ọkunrin yi. Nitori agbe-ago ọba li emi jẹ.

Neh 1