4. Nitori ọ̀pọlọpọ awọn panṣagà àgbere ti o roju rere gbà, iya ajẹ ti o ntà awọn orilẹ-ède nipasẹ̀ panṣaga rẹ̀, ati idile nipasẹ̀ ajẹ rẹ̀.
5. Kiyesi i, emi dojukọ́ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ká aṣọ itẹlẹ̀di rẹ li oju rẹ, emi o si fi ihòho rẹ hàn awọn orilẹ-ède, ati itiju rẹ hàn awọn ilẹ̀ ọba.
6. Emi o da ẹgbin ti o ni irira si ọ lara, emi o si sọ ọ di alaimọ́, emi o si gbe ọ kalẹ bi ẹni ifiṣẹlẹyà.
7. Yio si ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ yio sa fun ọ, nwọn o si wipe, A ti fi Ninefe ṣòfo: tani yio kẹdùn rẹ̀? nibo ni emi o ti wá olutùnu fun ọ?
8. Iwọ ha sàn jù No-ammoni, eyiti o wà lãrin odò ti omi yika kiri, ti agbara rẹ̀ jẹ okun, ti odi rẹ̀ si ti inu okun jade wá?
9. Etiopia ati Egipti li agbara rẹ̀, kò si li opin; Puti ati Lubimu li awọn olùranlọwọ rẹ.