Nah 3:17-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Awọn alade rẹ dabi eṣú, awọn ọgagun rẹ si dabi ẹlẹngà nla, eyiti ndó sinu ọgbà la ọjọ otutù, ṣugbọn nigbati õrùn là, nwọn sa lọ, a kò si mọ̀ ibiti wọn gbe wà.

18. Awọn olùṣọ agùtan rẹ ntõgbe, Iwọ ọba Assiria: awọn ọlọla rẹ yio ma gbe inu ekuru: awọn enia rẹ si tuka lori oke-nla, ẹnikan kò si kó wọn jọ.

19. Kò si ipajumọ fun ifarapa rẹ; ọgbẹ rẹ kún fun irora, gbogbo ẹniti o gbọ́ ihin rẹ yio pàtẹwọ le ọ lori, nitori li ori tani ìwa-buburu rẹ kò ti kọja nigbagbogbo?

Nah 3