Mik 6:11-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ki emi ha kà wọn si mimọ́ pẹlu òṣuwọ̀n buburu, ati pẹlu àpo òṣuwọ̀n ẹ̀tan?

12. Ti awọn ọlọrọ̀ rẹ̀ kún fun ìwa-ipá, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ ti sọ̀rọ eké, ahọn wọn si kún fun ẹ̀tan li ẹnu wọn.

13. Nitorina pẹlu li emi o ṣe mu ọ ṣàisan ni lilù ọ, ni sisọ ọ dahoro nitori ẹ̀ṣẹ rẹ.

14. Iwọ o jẹun, ṣugbọn iwọ kì yio yo; idábẹ yio wà lãrin rẹ; iwọ o kó kuro, ṣugbọn iwọ kì o lọ lailewu; ati eyi ti o kó lọ li emi o fi fun idà.

15. Iwọ o gbìn, ṣugbọn iwọ kì yio ká; iwọ o tẹ̀ igi olifi, ṣugbọn iwọ kì o fi ororo kunra; ati eso àjara, sugbọn iwọ kì o mu ọti-waini.

16. Nitori ti a pa aṣẹ Omri mọ́, ati gbogbo iṣẹ ile Ahabu, ẹ si rìn ni ìmọ wọn; ki emi ba le sọ ọ di ahoro, ati awọn ti ngbe inu rẹ di ẹ̀gan: ẹnyin o si rù ẹgan enia mi.

Mik 6