Dide, si ma pakà, Iwọ ọmọbinrin Sioni: nitori emi o sọ iwo rẹ di irin, emi o si sọ patakò rẹ di idẹ, iwọ o si run ọ̀pọlọpọ enia womu-womu: emi o si yá ère wọn sọtọ̀ fun Oluwa, ati iní wọn si Oluwa gbogbo aiye.