Mik 1:12-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nitori ara Maroti nreti ire, ṣugbọn ibi sọkalẹ ti ọdọ Oluwa wá si ẹnu bode Jerusalemu.

13. Iwọ ara Lakiṣi, di kẹkẹ mọ ẹranko ti o yara: on ni ibẹrẹ ẹ̀ṣẹ si ọmọbinrin Sioni: nitori a ri irekọja Israeli ninu rẹ.

14. Nitorina ni iwọ o ṣe fi iwe ikọ̀silẹ fun Moreṣetigati: awọn ile Aksibi yio jẹ eke si awọn ọba Israeli.

15. Sibẹ̀ emi o mu arole kan fun ọ wá, Iwọ ara Mareṣa: ogo Israeli yio wá si Adullamu.

16. Sọ ara rẹ di apari, si rẹ́ irun rẹ nitori awọn ọmọ rẹ ẹlẹgẹ́; sọ apári rẹ di gbòro bi idì; nitori a dì wọn ni igbèkun lọ kuro lọdọ rẹ.

Mik 1