Mat 3:13-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nigbana ni Jesu ti Galili wá si Jordani sọdọ Johanu lati baptisi lọdọ rẹ̀.

14. Ṣugbọn Johanu kọ̀ fun u, wipe, Emi li a ba baptisi lọdọ rẹ, iwọ si tọ̀ mi wá?

15. Jesu si dahùn, o wi fun u pe, jọwọ rẹ̀ bẹ̃ na: nitori bẹ̃li o yẹ fun wa lati mu gbogbo ododo ṣẹ. Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀.

Mat 3