Mat 28:16-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mọkanla jade lọ si Galili, si ori òke ti Jesu ti sọ fun wọn.

17. Nigbati nwọn si ri i, nwọn foribalẹ fun u: ṣugbọn awọn miran ṣiyemeji.

18. Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi.

19. Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmí Mimọ́:

20. Ki ẹ ma kọ́ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye. Amin.

Mat 28