Mat 27:41-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu awọn akọwe, ati awọn àgbãgba nfi ṣe ẹlẹya, wipe,

42. O gbà awọn ẹlomiran là; ara rẹ̀ ni kò le gbalà. Ọba Israeli sa ni iṣe, jẹ ki o sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, awa o si gbà a gbọ́.

43. O gbẹkẹle Ọlọrun; jẹ ki o gbà a là nisisiyi, bi o ba fẹran rẹ̀: o sá wipe, Ọmọ Ọlọrun li emi.

44. Awọn olè ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nfi eyi na gún u loju bakanna.

45. Lati wakati kẹfa, ni òkunkun ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan.

46. Niwọn wakati kẹsan ni Jesu si kigbe li ohùn rara wipe, Eli, Eli, lama sabaktani? eyini ni, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ?

47. Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọkunrin yi npè Elijah.

48. Lojukanna ọkan ninu wọn si sare, o mu kànìnkànìn, o tẹ̀ ẹ bọ̀ inu ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o si fifun u mu.

Mat 27