7. Nigbana ni gbogbo awọn wundia wọnni dide, nwọn, si tún fitila wọn ṣe.
8. Awọn alaigbọn si wi fun awọn ọlọgbọn pe, Fun wa ninu oróro nyin; nitori fitila wa nkú lọ.
9. Ṣugbọn awọn ọlọ́gbọn da wọn li ohùn, wipe, Bẹ̃kọ; ki o má ba ṣe alaito fun awa ati ẹnyin: ẹ kuku tọ̀ awọn ti ntà lọ, ki ẹ si rà fun ara nyin.
10. Nigbati nwọn si nlọ rà, ọkọ iyawo de; awọn ti o si mura tan bá a wọle lọ si ibi iyawo: a si tì ilẹkun.
11. Ni ikẹhin li awọn wundia iyokù si de, nwọn nwipe, Oluwa, Oluwa, ṣilẹkun fun wa.