Mat 25:37-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

37. Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu?

38. Nigbawo li awa ri ọ li alejò, ti a gbà ọ si ile? tabi ti iwọ wà ni ìhoho, ti awa daṣọ bò ọ?

39. Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? tabi ti iwọ wà ninu tubu, ti awa si tọ̀ ọ wá?

40. Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi.

41. Nigbana ni yio si wi fun awọn ti ọwọ́ òsi pe, Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ̀:

42. Nitori ebi pa mi, ẹnyin kò si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin kò si fun mi li ohun mimu:

Mat 25