Mat 25:34-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ́ ọtun rẹ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pèse silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa:

35. Nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejò, ẹnyin si gbà mi si ile:

36. Mo wà ni ìhoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ̀ mi wá.

37. Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu?

38. Nigbawo li awa ri ọ li alejò, ti a gbà ọ si ile? tabi ti iwọ wà ni ìhoho, ti awa daṣọ bò ọ?

39. Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? tabi ti iwọ wà ninu tubu, ti awa si tọ̀ ọ wá?

40. Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi.

41. Nigbana ni yio si wi fun awọn ti ọwọ́ òsi pe, Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ̀:

42. Nitori ebi pa mi, ẹnyin kò si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin kò si fun mi li ohun mimu:

43. Mo jẹ alejò, ẹnyin kò gbà mi si ile: mo wà ni ìhoho, ẹnyin kò si daṣọ bò mi: mo ṣàisan, mo si wà ninu tubu, ẹnyin kò bojuto mi.

Mat 25