26. Oluwa rẹ̀ si dahùn o wi fun u pe, Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra, iwọ mọ̀ pe emi nkore nibiti emi kò funrugbin si, emi si nṣà nibiti emi kò fẹ́ka si:
27. Nitorina iwọ iba fi owo mi si ọwọ́ awọn ti npowodà, nigbati emi ba de, emi iba si gbà nkan mi pẹlu elé.
28. Nitorina ẹ gbà talenti na li ọwọ́ rẹ̀, ẹ si fifun ẹniti o ni talenti mẹwa.
29. Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, li a o fifun, yio si ni lọpọlọpọ: ṣugbọn li ọwọ́ ẹniti kò ni li a o tilẹ gbà eyi ti o ni.
30. Ẹ si gbé alailere ọmọ-ọdọ na sọ sinu òkunkun lode: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.
31. Nigbati Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mimọ́ pẹlu rẹ̀, nigbana ni yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀:
32. Niwaju rẹ̀ li a o si kó gbogbo orilẹ ède jọ: yio si yà wọn si ọ̀tọ kuro ninu ara wọn gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iyà agutan rẹ̀ kuro ninu ewurẹ:
33. On o si fi agutan si ọwọ́ ọtún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ́ òsi.
34. Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ́ ọtun rẹ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pèse silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa: