1. NIGBANA li a o fi ijọba ọrun wé awọn wundia mẹwa, ti o mu fitila wọn, ti nwọn si jade lọ ipade ọkọ iyawo.
2. Marun ninu wọn ṣe ọlọgbọn, marun si ṣe alaigbọn.
3. Awọn ti o ṣe alaigbọ́n mu fitila wọn, nwọn kò si mu oróro lọwọ:
4. Ṣugbọn awọn ọlọgbọn mu oróro ninu kolobo pẹlu fitila wọn.
5. Nigbati ọkọ iyawo pẹ, gbogbo wọn tõgbé, nwọn si sùn.
6. Ṣugbọn lãrin ọganjọ, igbe ta soke, wipe, Wo o, ọkọ, iyawo mbọ̀; ẹ jade lọ ipade rẹ̀.
7. Nigbana ni gbogbo awọn wundia wọnni dide, nwọn, si tún fitila wọn ṣe.