6. Nwọn fẹ ipò ọlá ni ibi ase, ati ibujoko ọla ni sinagogu,
7. Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi.
8. Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin.
9. Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun.
10. Ki a má si ṣe pè nyin ni olukọni: nitori ọkan li Olukọni nyin, ani Kristi.
11. Ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin, on ni yio jẹ iranṣẹ nyin.
12. Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ li a o gbé ga.
13. Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin sé ijọba ọrun mọ́ awọn enia: nitori ẹnyin tikaranyin kò wọle, bẹ̃li ẹnyin kò jẹ ki awọn ti nwọle ki o wọle.