Mat 23:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nyi okun ati ilẹ ká lati sọ enia kan di alawọṣe; nigbati o ba si di bẹ̃ tan, ẹnyin a sọ ọ di ọmọ ọrun apadi nigba meji ju ara nyin lọ.

16. Egbé ni fun nyin, ẹnyin amọ̀na afọju, ti o nwipe, Ẹnikẹni ti o ba fi tẹmpili bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi wura tẹmpili bura, o di ajigbese.

17. Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, wura, tabi tẹmpili ti nsọ wura di mimọ́?

18. Ati pe, Ẹnikẹni ti o ba fi pẹpẹ bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi ẹ̀bun ti o wà lori rẹ̀ bura, o di ajigbese.

19. Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, ẹ̀bun, tabi pẹpẹ ti nsọ ẹ̀bun di mimọ́?

20. Njẹ ẹniti o ba si fi pẹpẹ bura, o fi i bura, ati ohun gbogbo ti o wà lori rẹ̀.

21. Ẹniti o ba si fi tẹmpili bura, o fi i bura, ati ẹniti o ngbé inu rẹ̀.

22. Ẹniti o ba si fi ọrun bura, o fi itẹ́ Ọlọrun bura, ati ẹniti o joko lori rẹ̀.

23. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi agabagebe; nitoriti ẹnyin ngbà idamẹwa minti, ati anise, ati kumini, ẹnyin si ti fi ọ̀ran ti o tobiju ninu ofin silẹ laiṣe, idajọ, ãnu, ati igbagbọ́: wọnyi li o tọ́ ti ẹnyin iba ṣe, laisi fi iyoku silẹ laiṣe.

24. Ẹnyin afọju amọ̀na, ti nsẹ́ kantikanti ti o si ngbé ibakasiẹ mì.

25. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nfọ̀ ode ago ati awopọkọ́ mọ́, ṣugbọn inu wọn kún fun irẹjẹ ati wọ̀bia.

Mat 23